ARE-OJE
Egungun yi sora re
Egun bi eyin osi
Egungun yi fura sirare
Okuta bikaun osi
Egungun makoja aye re
Iyo loga awon yerupe
Egungun yi mo iwo ara re
Egungun bi Lebe siTani je foju di Ladogba
Ninu egungun.
Ajobiewe akoni onijo ni
Oga olokiti si ni Dasofunjo
Ile gbogbo won Loje
Ti o ni ogba oro.
Ojetunde agbo ile Alagbaa
Lo to wa.
Se bi baba egungun ni
Ile ti won se.
Ba ba mo ki, Are-oje egungun
Olori gbogbo areku jaye ni.
Are-oje o!
Ojelarinnaka o wa moju to
Awon omo re ti nrin ihoho
Woja yi.
Omode iwoyi o naani a nwoso
Reja mo, ekisa loku ti won wo.
Are-oje o !
Ojekomologbon o wa mu atori
Fun omo alainitiju ti nboju bora
Wa atori na awon alawose ti won ba oje lojuje.
Are-oje o!
Ojerinde omo aku lodo ma fara kan omi.
Igbori,
Omo ku nile kodaa pon
Oku eko awon ni ijagudu akara.
E fakara bomode tagba
Ki e fi Eko kowon logbon asa.
Sebi odundun le ndaso fegun
Ti ngbagere lara won.
Are-oje o!
Ke si, Are-ilu ko filu kowa lasa igbaye.
Are-ilu ki opa bolu
O nfi oku ewure soro oni,
"Dan didi danu danu dan dan
Danu dan danu dan danu du dan Dan danu dani danu
Dan Didi danu danu dan dan"
"Egungun o mo owo ara re
O nlo si oja o wa tun fa
Ganmu ganmu lowo
Egungun o mo owo ara re"
Egungun de
Akomo lasa de
Dasofunjo de.
Comments
Post a Comment